ÈWÌ Láti ọwọ Àbàlú Khadijat Opẹ́yemí
Ìbà elédùmarè
Ọba tí ń bẹ kí bẹbẹ ó tó máa bẹ,
Mo ṣèbà ẹ̀yin àgbààgbà tí ń bẹ nílẹ̀ yí,
Ìbà ọkùnrin, ìbà obìnrin,
Nítorí b’ọ́mọdé bá fẹ́ pẹ́ láyé
Dandan ni kó wárí fún gbogbo ajunilọ,
Mo júbà k’íbà mi o ṣẹ o.
Ẹnì bá léti’nú ẹ wá,
Gbogbo ẹ́yin ọ̀jọ̀gbọ́n pátápátá,
Ẹ f’ara balẹ̀ fún’mòràn tó gbọ̀nà ọ̀tun yọ.
Bàbá ń sáré k’o lè jéèyàn láyé,
Ìyá ń gbàdúrà k’o soríire,
Lọ́jọ́ t’o múra’lè’wé,
Gbogbo ẹbi ń dun-nún,
Ìyá ń sunkún, bàbá ń súre,
P’àyúnlọ àyúnbọ́ lọwọ́ ń y’ẹ́nu,
Wón kì ọ́ nílọ̀,
K’o mo ọmọ ẹni t’ó ń ṣe.
O delè’wé tán-án,
O di kenke bí ère,
Ààyé gbà ọ́ bíi jẹ̀díjẹ̀dí àsálẹ́,
O wá ń jayé ta ló fẹ́ mú mi si,
Òní patí, ọ̀la àríyá,
Gbogbo ọjọ́ ni bí ọdún,
Ayé ń yẹ́ ọ sí pé o dùn l’ọ́kùnrin,
Ò ń náwó bíi ẹlẹ́dàà,
O sì tún ń páwọ̀dà bí ọ̀gà.
Ọ̀rẹ́ wa, ọkọ young lady,
Jẹ́ k’á gbá ọ ní gbólóhùn ewì díẹ̀ kórí ó pé wálé,
Irú u yín le tìbàdàn b’óbìnrin rèkó ó,
Níbi k’ómoge ó kọjá tán
Kí ẹ máa fojú léwọn kiri,
Ká wo’bìnrin fẹ̀fẹ̀ bi ẹní fojúkan màláíkà,
Wón ń wò ọ́ láwò sunkún, ò ń wo ra’rẹ láwò rẹ́rìn-ín.
Apónbéporẹ́, ìbàdí-àrán,
O ṣọra à rẹ d’àkìtàn ò kọlẹ̀ kílẹ́,
Bí dúdú ṣe ń gbé ọ ni pupa ń sọ̀ ọ́ kalẹ́
O sọ nàbì diṣẹ́
O gbàgbé b’o ṣe fi ilé sílẹ̀ lọ́jọ́ ọjọ́sí,
O gbàgbé gbogbo ìléríì rẹ,
O gbàgbé oun tó gbé ọ wá sílẹ̀ yí,
O jẹ́ ronú pìwà dà kó tó jìnnà,
Nítorí bi’di bá bàjẹ́ tán án,
Ti onìdí ní ó dà b’ódọla.
Ìgbà ara làá búra,
Ẹnìkan kìí bú Sàngó nígbá òjò,
Ìgbẹ̀yìn níí dun olókù àdá
Ọjọ́ ọdún n lọ̀rọ̀ ń dun ọ̀lẹ,
Ààbò ọ̀rọ̀ tó f’ọ́molúàbí,
Tó bá dénú ẹ̀ yí ò d’odidi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *